Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 23:11-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.

12. Fi àyà sí ẹ̀kọ́,àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.

13. Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé,nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.

14. Bí ìwọ fi pàṣán nà án,ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run-àpáàdì.

15. Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n,ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.

16. Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.

17. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa,ní ọjọ́ gbogbo.

18. Nítorí pé ìkẹyìn ń bẹ nítòótọ́;ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.

19. Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.

20. Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí;àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;

21. Nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di talákà;ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.

22. Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó

23. Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́, àti òye.

24. Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi:ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n,yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.

25. Jẹ́ kí bàbá rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀,sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.

26. Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi,kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú-dídùn sí ọ̀nà mi.

Ka pipe ipin Òwe 23