Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 23:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,kíyèsí ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.

2. Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.

3. Má ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀:nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.

4. Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀:síwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ.

5. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́-apá fún ara rẹ̀,ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.

6. Má ṣe jẹ oúnjẹ olójú búburú,bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀.

7. Nítorí pé bí ẹni tí ń sírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí:“Má a jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ;ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ.

8. Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde,ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.

9. Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè (òmùgọ̀);nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.

10. Má ṣe sí ààlà àtijọ́ kúrò;má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.

11. Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.

12. Fi àyà sí ẹ̀kọ́,àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.

13. Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé,nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.

Ka pipe ipin Òwe 23