20. Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradárasí ọ níti ìmọ̀ràn àti níti ẹ̀kọ́,
21. Kí ó lè mú ọ mọ dídájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ?
22. Má ṣe ja talákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ talákà:bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè:
23. Nítorí Olúwa yóò gbéjà wọn,yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
24. Má ṣe bá oníbìínu ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
25. Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀,ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
26. Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀wọ́,tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
27. Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi ṣan,nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹní rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
28. Má ṣe yẹ ààlà ilẹ ìgbàanì,tí àwọn baba rẹ ti pa.
29. Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.