Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 22:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọ pọ̀: Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.

3. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n níyà.

4. Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.

5. Ègún àti ìdẹkun ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.

6. Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.

7. Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú,ajigbésè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.

8. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká aṣán:ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.

9. Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún;nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.

10. Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde;nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.

11. Ẹni tí ó fẹ́ ìwà-funfun ti àyà,tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.

12. Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́,ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.

Ka pipe ipin Òwe 22