Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 20:26-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ọlọgbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.

27. Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàna máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú

28. Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.

29. Ògo ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn jẹ́ewú orí ni iyì arúgbó.

30. Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ,pàsán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.

Ka pipe ipin Òwe 20