Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 20:2-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún;ẹnikẹ́ni tí ó bá mú-un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.

3. Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjàṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

4. Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹnítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

5. Ètè ọkàn ènìyàn dàbí, omi jínjìn;ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.

6. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń wí oore wọn jáde,ṣùgbọ́nn kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòótọ́.

7. Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkùìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

8. Nígbà tí ọba bá jókóò sórí ilẹ̀ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.

9. Táni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

10. Ìdíwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.

11. Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.

12. Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran Olúwa ni ó dá méjèèjì.

13. Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di talákàmá ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.

14. “Kò dára, kò dára” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wínígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán, yóò máayangàn bí òun tí ṣe rí i rà sí.

15. Góòlù wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.

16. Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò;mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.

17. Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà ẹ̀rú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyànṣùgbọ́n, a yọrí sí bi ẹnu tí ó kún fún èèpẹ̀.

18. Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀rànbí o bá ń jagun, gba ìtọ́ṣọ́nà.

19. Olófòófó dalẹ̀ àsírínítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ jù.

Ka pipe ipin Òwe 20