Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 20:16-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò;mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.

17. Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà ẹ̀rú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyànṣùgbọ́n, a yọrí sí bi ẹnu tí ó kún fún èèpẹ̀.

18. Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀rànbí o bá ń jagun, gba ìtọ́ṣọ́nà.

19. Olófòófó dalẹ̀ àsírínítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ jù.

20. Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.

21. Ogún tí a kó jọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.

22. Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀ṣan àṣìṣe rẹ yìí fún ọ”Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.

23. Olúwa kórìíra òdiwọ̀n èké.Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.

24. Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyànBáwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?

25. Ìdẹkùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíánígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.

26. Ọlọgbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.

Ka pipe ipin Òwe 20