Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 20:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọ̀tí líleẹnikẹ́ni tí ó bá sìnà nìpaṣẹ̀ wọn kò gbọ́n.

2. Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún;ẹnikẹ́ni tí ó bá mú-un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.

3. Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjàṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

4. Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹnítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

5. Ètè ọkàn ènìyàn dàbí, omi jínjìn;ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.

6. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń wí oore wọn jáde,ṣùgbọ́nn kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòótọ́.

Ka pipe ipin Òwe 20