Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 2:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,

2. tí o tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́ntí o sì fi ọkàn rẹ sí òye,

3. bí ìwọ sì pè fún ojú inú rẹ rírantí o sì kígbe sókè fún òye

4. bí ìwọ bá wá ṣàfẹ́rì rẹ̀ bí i fàdákàtí o sì wa kiri bí i fún ohun iyebíye tó fara sin.

5. Nígbà náà ni òye ẹ̀rù Olúwa yóò yé ọ,tí ó sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.

6. Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá

7. Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,Òun ni aṣà fún àwọn tí ń rìn déédé,

8. ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

9. Nígbà náà ni òye ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì dára,tí ó dára yóò yẹ́ ọ—gbogbo ọ̀nà dídara.

10. Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ

11. Ara (ikú) sísọ ni yóò dáàbò bò ọÒye yóò sì pa ọ́ mọ́.

12. Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,

13. tí ó kúrò ní ọ̀nà tààràláti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,

Ka pipe ipin Òwe 2