Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 19:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọrọ̀ má a ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;ṣùgbọ̀n ọ̀rẹ́ ẹ talákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5. Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láì jìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

6. Ọ̀pọ̀ ń wá ojú rere Olórí;gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.

7. Gbogbo ará ilé e talákà ni ó pa á tìmélòómélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,kò tilẹ̀ rí wọn rárá.

8. Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.

9. Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyàẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.

10. Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọlá ńlá,mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jọba lórí ọmọ aládé.

11. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù;fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12. Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún,ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

13. Aláìgbọ́n ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀sọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

Ka pipe ipin Òwe 19