Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 19:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ọ̀lẹ ṣíṣẹ́ máa ń fa oorun sísùn fọnfọnfọnebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

16. Ẹni-kẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.

17. Ẹni tí ó ṣáànú talákà, Olúwa ní ó yáyóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.

18. Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú iparun un rẹ̀.

19. Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀bí ìwọ bá gbàá là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan síi.

20. Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

21. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyànṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

22. Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;ó sàn láti jẹ́ talákà ju òpùrọ́ lọ.

23. Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá:nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láì sí ewu.

24. Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 19