Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 19:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù;fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12. Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún,ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

13. Aláìgbọ́n ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀sọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

14. A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbíṣùgbọ́n aya olóye láti ọdọ̀ Olúwa ni.

15. Ọ̀lẹ ṣíṣẹ́ máa ń fa oorun sísùn fọnfọnfọnebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

Ka pipe ipin Òwe 19