Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 19:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sàn kí èèyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.

2. Kò dára láti ní ìtara láì ní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì sìnà.

3. Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;ṣíbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.

4. Ọrọ̀ má a ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;ṣùgbọ̀n ọ̀rẹ́ ẹ talákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5. Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láì jìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

6. Ọ̀pọ̀ ń wá ojú rere Olórí;gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.

7. Gbogbo ará ilé e talákà ni ó pa á tìmélòómélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,kò tilẹ̀ rí wọn rárá.

8. Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.

9. Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyàẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.

10. Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọlá ńlá,mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jọba lórí ọmọ aládé.

11. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù;fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12. Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún,ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

Ka pipe ipin Òwe 19