Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 14:9-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Aláìgbọ́n ń ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n láàrin àwọn olódodo ni a ti rí ojú rere.

10. Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀kò sì sí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.

11. A ó pa ilé ènìyàn búburú runṢùgbọ́n àgọ́ Olódodo yóò máa gbèrú síi.

12. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa já sí ikú.

13. Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìnín, ọkàn leè máa kérora;ayọ̀ sì leè yọrí sí ìbànújẹ́.

14. A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀Ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.

15. Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ṣùgbọ́n Olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbéṣẹ̀ rẹ̀.

16. Ọlọgbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibiṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.

17. Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,a sì kórìíra eléte ènìyàn:

18. Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ṣùgbọ́n a dé ọlọgbọ́n ní adé ìmọ̀.

19. Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rereàti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.

20. Kódà àwọn aládùúgbò o talákà kò fẹ́ràn rẹ̀ṣùgbọ́n, Ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.

21. Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.

Ka pipe ipin Òwe 14