21. Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.
22. Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í sìnà?Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbérò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́.
23. Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wáṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.
24. Ọrọ̀ Ọlọgbọ́n ènìyàn ni adé orí wọnṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.
25. Ẹlẹ́rìí tí ó ṣòótọ́ gba ẹ̀mí làṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.
26. Ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa ni ilé ìṣọ́ ààbòyóò sì tún jẹ́ ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.
27. Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ oríṣun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
28. Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo Ọba,ṣùgbọ́n láì sí ìjòyè, Ọba á parun.
29. Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,ṣùgbọ́n onínú fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
30. Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
31. Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hànṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
32. Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.