Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 14:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,ṣùgbọ́n aláìgbọ́n obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ wó o.

2. Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa,ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.

3. Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàsán fún ẹ̀yìn rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.

4. Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóníṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.

5. Ẹlẹ́rìí tí ń sòótọ́ kì í tan niṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.

6. Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

7. Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.

8. Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà an wọnṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ asìwèrè ni ìtànjẹ.

9. Aláìgbọ́n ń ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n láàrin àwọn olódodo ni a ti rí ojú rere.

10. Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀kò sì sí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.

11. A ó pa ilé ènìyàn búburú runṢùgbọ́n àgọ́ Olódodo yóò máa gbèrú síi.

12. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa já sí ikú.

13. Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìnín, ọkàn leè máa kérora;ayọ̀ sì leè yọrí sí ìbànújẹ́.

14. A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀Ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 14