Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 12:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. A sí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;ṣùgbọ́n ilé Olódodo dúró ṣinṣin.

8. A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.

9. Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láì lóúnjẹ.

10. Ènìyàn rere ń ṣaájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílòÀmọ́ ìwà tó dára jù tí ènìyàn búburú lè hù, ibi ni.

11. Ẹni tí ó bá dáko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásánlàsàn kò gbọ́n.

12. Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógún àwọn ènìyàn ìkàṣùgbọ́n gbòǹgbò Olódodo ń gbilẹ̀.

13. A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n Olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdàámú.

14. Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rerebí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.

15. Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ṣùgbọ́n Ọlọgbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.

16. Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀,ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.

17. Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí tòótọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ ríṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.

18. Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọgbọ́n ń mú ìwòsàn wá.

Ka pipe ipin Òwe 12