Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 12:23-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ènìyàn Olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.

24. Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jọbaṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí sínsìnrú.

25. Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodòṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.

26. Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn sìnà.

27. Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.

28. Ní ọ̀nà àwọn Olódodo ni ìyè wàní ọ̀nà náà ni àìkú wà.

Ka pipe ipin Òwe 12