Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 11:9-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Aláìmọ̀ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ Olódodo sá àsálà.

10. Nígbà tí Olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.

11. Nípaṣẹ̀ ìbùkún, Olódodo a gbé ìlú ga:ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

12. Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

13. Olófòófó tú àsírí ìkọ̀kọ̀ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àsírí mọ́.

14. Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀ èdè ṣubúṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.

15. Ẹni tí ó ṣe onídùúró fún ẹlòmíràn yóò jìyà dájúdájú,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onídùúró yóò wà láì léwu.

16. Obìnrin oníwà rere gba ìyìnṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.

17. Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóoreṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.

18. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

19. Olódodo tòótọ́ rí ìyèṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.

20. Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburúṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.

21. Mọ èyí dájú pé: ènìyàn búburú kì yóò lọ láì jìyà,ṣùgbọ́n àwọn Olódodo yóò lọ láì jìyà.

22. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.

Ka pipe ipin Òwe 11