Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 11:17-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóoreṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.

18. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

19. Olódodo tòótọ́ rí ìyèṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.

20. Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburúṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.

21. Mọ èyí dájú pé: ènìyàn búburú kì yóò lọ láì jìyà,ṣùgbọ́n àwọn Olódodo yóò lọ láì jìyà.

22. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.

23. Ìfẹ́ inú Olódodo yóò yọrí sí ohun rereṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.

24. Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i;òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.

25. Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i;ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.

26. Àwọn ènìyàn a ṣépè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.

27. Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rereṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.

28. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú;ṣùgbọ́n Olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.

Ka pipe ipin Òwe 11