Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 11:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nípaṣẹ̀ ìbùkún, Olódodo a gbé ìlú ga:ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

12. Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

13. Olófòófó tú àsírí ìkọ̀kọ̀ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àsírí mọ́.

14. Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀ èdè ṣubúṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.

15. Ẹni tí ó ṣe onídùúró fún ẹlòmíràn yóò jìyà dájúdájú,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onídùúró yóò wà láì léwu.

16. Obìnrin oníwà rere gba ìyìnṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.

17. Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóoreṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.

18. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

19. Olódodo tòótọ́ rí ìyèṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 11