Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 11:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa kórìíra òṣùwọ̀n èkéṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.

2. Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì déṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.

3. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìsòótọ́ wọn.

4. Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínúṣùgbọ́n òdodo a máa gba ni lọ́wọ́ ikú.

5. Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọnṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fàá lulẹ̀.

6. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n làṣùgbọ́n ìdẹkùn ètè búburú mú aláìsòótọ́.

7. Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parungbogbo ohun tó ń fojú sọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já sófo.

8. A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibidípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú.

9. Aláìmọ̀ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ Olódodo sá àsálà.

Ka pipe ipin Òwe 11