Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 10:7-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkúnṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.

8. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

9. Ẹni oníwà títọ́ ń rìn láìléwuṣùgbọ́n àsírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

10. Ẹni tí ń sẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkànAláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.

11. Ẹnu Olódodo jẹ́ oríṣun ìyèṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.

12. Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

13. Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóyeṣùgbọ́n kùmọ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

14. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

15. Ọrọ̀ àwọn Olódodo ni ìlú olódi wọn,ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.

16. Èrè Olódodo ń mú ìyè wá fún wọnṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.

17. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hànṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn sìnà.

18. Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ẹni tí ó sì ń báni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.

19. Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kùṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

20. Ètè Olódodo jẹ́ àṣàyan fàdákàṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn buburú kò níye lórí.

Ka pipe ipin Òwe 10