25. Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.
26. Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojúbẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.
27. Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.
28. Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.
29. Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún Olódodo,ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi.
30. A kì yóò fa Olódodo tu láéláéṣùgbọ́n ènìyàn buburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
31. Ẹnu Olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.
32. Ètè Olódodo mọ ohun tí ó tọ́,ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.