Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 10:24-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

25. Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

26. Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojúbẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.

27. Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

28. Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.

29. Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún Olódodo,ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi.

30. A kì yóò fa Olódodo tu láéláéṣùgbọ́n ènìyàn buburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

31. Ẹnu Olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

32. Ètè Olódodo mọ ohun tí ó tọ́,ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.

Ka pipe ipin Òwe 10