Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 10:21-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ètè Olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.

22. Ìbùkún Olúwa ń mú ọrọ̀ wá,kì í sìí fi ìdàámú sí i.

23. Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburúṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.

24. Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

25. Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

26. Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojúbẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.

27. Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

28. Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.

29. Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún Olódodo,ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi.

30. A kì yóò fa Olódodo tu láéláéṣùgbọ́n ènìyàn buburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 10