2. Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrèṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
3. Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa Olódodoṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
4. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di talákà,ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra síṣẹ́ a máa sọni di ọlọ́rọ̀.
5. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ọmọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.
6. Ìbùkún ní ó máa ń kún orí Olódodoṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.
7. Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkúnṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.
8. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.
9. Ẹni oníwà títọ́ ń rìn láìléwuṣùgbọ́n àsírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.
10. Ẹni tí ń sẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkànAláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.
11. Ẹnu Olódodo jẹ́ oríṣun ìyèṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.
12. Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.
13. Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóyeṣùgbọ́n kùmọ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.
14. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.