Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 10:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn òwe Sólómónì:Ọlọgbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùnṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

2. Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrèṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

3. Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa Olódodoṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

4. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di talákà,ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra síṣẹ́ a máa sọni di ọlọ́rọ̀.

5. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ọmọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

6. Ìbùkún ní ó máa ń kún orí Olódodoṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.

7. Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkúnṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.

8. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

9. Ẹni oníwà títọ́ ń rìn láìléwuṣùgbọ́n àsírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

10. Ẹni tí ń sẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkànAláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.

Ka pipe ipin Òwe 10