Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 1:8-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹmá ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá ọ̀ rẹ sílẹ̀

9. Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòrùn dídùn lórí rẹàti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.

10. Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,má ṣe gbà fún wọn.

11. Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa kálọ;jẹ́ ká ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,jẹ́ ká dá àwọn aláìlera kan lọ́nà;

12. Jẹ́ ká gbé wọn mì láàyè, bí ibojì òkú,àti lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;

13. A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lóría ó sì fi ìkógún kún inú ilé wa;

14. Dara pọ̀ mọ́ wa,a ó sì jọ powó sínú àpò kan náà”

15. Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;

16. Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

17. Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ okùn de ẹyẹ,ní ìṣojú u gbó ẹyẹ!

18. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.Ara wọn ni wọ́n ń dá lóhùn

19. Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọÌkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀

20. Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópóó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrin ọjà;

21. Láàrin ọjà ni ó ti kígbe jádeNí ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:

Ka pipe ipin Òwe 1