Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 1:12-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Jẹ́ ká gbé wọn mì láàyè, bí ibojì òkú,àti lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;

13. A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lóría ó sì fi ìkógún kún inú ilé wa;

14. Dara pọ̀ mọ́ wa,a ó sì jọ powó sínú àpò kan náà”

15. Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;

16. Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

17. Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ okùn de ẹyẹ,ní ìṣojú u gbó ẹyẹ!

18. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.Ara wọn ni wọ́n ń dá lóhùn

19. Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọÌkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀

20. Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópóó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrin ọjà;

21. Láàrin ọjà ni ó ti kígbe jádeNí ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:

22. “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ́kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó?Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó?Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?

23. Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni,Ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yínkí n sì fi inú un mi hàn sí i yín.

24. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pèkò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo háwọ́ sí wọn,

25. Níwọ̀n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mití ẹ kò sì ní gba ìbáwí mi

26. Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ínN ó sẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín

27. Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle,Nígbà tí ìdàámú bá dé bá ọ bí ààjà,nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.

28. “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn;wọn yóò farabalẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.

Ka pipe ipin Òwe 1