Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 7:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tóbáwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́!

7. Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,àti ọmú rẹ bí idì èso àjàrà.

8. Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ;Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú”Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,Àti èémi imú rẹ bí i ápù.

9. Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.Tí ó kúnná tí ó sì dùn,tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀

10. Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,èmí sì ni ẹni tí ó wù ú.

11. Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,Jẹ́ kí a lo àṣálẹ̀ ní àwọn ìletò

12. Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtùláti wo bí àjàrà rúwébí ìtànná àjàrà bá là.Àti bí póméegíránéètì bá ti rúdí,níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.

13. Àwọn èṣo mánídárákì mú òórùn wọn jádení ẹnu ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso,èso ọ̀tún àti àkúgbótí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 7