Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 5:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;mo ti kó òjíá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́

2. Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.Gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ilẹ̀kùn.“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,àdàbà mi, aláìlábàwọ́n miOrí mi kún fún omi ìrì,irun mi kún fún òtútù òru.”

3. Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà miṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?Mo ti wẹ ẹsẹ̀ miṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?

4. Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ilẹ̀kùninú mi sì yọ́ sí i

5. Èmi dìde láti sílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,òjíá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,òjíá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń ṣànsí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn

6. Èmi sí ilẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 5