Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 4:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ẹyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbòtí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yàgàn.

3. Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;Ẹnu rẹ̀ dùn.Èrẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pàmógíránéètìlábẹ́ ìbòjú rẹ

4. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dáfídì,tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́,gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.

5. Ọmú rẹ méjèèjì dàbí ọmọ ẹgbin méjìtí wọ́n jẹ́ ìbejìtí ń jẹ láàrin ìtànná lílì.

6. Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀tí òjìji yóò fi fò lọ,Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjíáàti sí òkè kékeré tùràrí.

7. Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwa, olùfẹ́ mi;kò sì sí àbàwọ́n lára rẹ.

8. Kí a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì, ìyàwó mi,ki a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì.Àwa wò láti orí òkè Ámánà,láti orí òkè ti Ṣénírì, àti téńté Hérímónì,láti ibi ihò àwọn kìnnìún,láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

9. Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;Ìwọ ti gba ọkàn mipẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ,

10. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!

11. Ètè rẹ ń kán dídùn afárá oyin, ìyàwó mi;wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lébánónì.

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 4