Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olùfẹ́ mi!Áá à ìwọ jẹ́ arẹwà.Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹIrun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.Tí ó sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè Gílíádì.

2. Ẹyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbòtí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yàgàn.

3. Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;Ẹnu rẹ̀ dùn.Èrẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pàmógíránéètìlábẹ́ ìbòjú rẹ

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 4