Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 2:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kékèké

9. Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrínWò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri waÓ yọjú ní ojú fèrèséÓ ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà

10. Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,“Dìde, Olùfẹ́ mi,Arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.

11. Wò ó! Ìgbà otútù ti kọjá;Òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 2