Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi ni ìtànná ṢárónìBí ìtàná lílì àwọn àfonífojì

2. Bí ìtànná lílì ní àárin ẹ̀gúnni olùfẹ́ mi ní àárin àwọn wúndíá.

3. Bí igi ápù láàrin àwọn igi inú igbó,ni olùfẹ́ mí láàrin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrinMo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀,Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.

4. Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àṣè,Ìfẹ́ sì ni ọ̀pàgun rẹ̀ lórí mi.

5. Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró.Fi èṣo ápù tù mi láraNítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.

6. Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí miỌwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 2