Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 1:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Bí ìwọ kò bá mọ̀,Ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.Bá ọ̀nà ti agbo ẹran rìn lọ.Kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùsọ́ àgùntàn.

9. Olùfẹ́ mi,Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò.

10. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀

11. A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,A ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.

12. Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀.Òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 1