Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 1:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdúNítorí òòrùn mú mi dúdúỌmọkùnrin ìyá mi bínú símiÓ sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà.Ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú

7. Ṣọ fún mi ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,Níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán.Kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin aṣánNí ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

8. Bí ìwọ kò bá mọ̀,Ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.Bá ọ̀nà ti agbo ẹran rìn lọ.Kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùsọ́ àgùntàn.

9. Olùfẹ́ mi,Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò.

10. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀

11. A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,A ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.

12. Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀.Òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.

13. Ìdì òjíá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi.Òun ó sinmi lé àárin ọmú mi.

14. Bí ìdì ìtàná Hénínà ni Olùfẹ́ mi rí sí miLáti inú ọgbà àjàrà ti Énígédì.

15. Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olùfẹ́ mi!Áá à, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.

16. Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!Áá à, Báwo ni o ṣe wu ni!Ibùsùn wa ní ìtura.

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 1