Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Orin àwọn orin tí i ṣe orin Sólómónì

2. Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.

3. Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jádeAbájọ tí àwọn wúndíá fi fẹ́ ọ.

4. Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíáỌba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!

5. Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,Dúdú bí àgọ́ KédárìBí àgọ́ aṣọ kọ́tìnnì ti Sólómónì

6. Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdúNítorí òòrùn mú mi dúdúỌmọkùnrin ìyá mi bínú símiÓ sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà.Ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú

7. Ṣọ fún mi ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,Níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán.Kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin aṣánNí ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

8. Bí ìwọ kò bá mọ̀,Ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.Bá ọ̀nà ti agbo ẹran rìn lọ.Kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùsọ́ àgùntàn.

9. Olùfẹ́ mi,Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò.

10. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 1