Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 8:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ta ni ó dàbí ọlọgbọ́n ènìyàn?Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo?Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dánó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.

2. Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run.

3. Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró ní ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.

4. Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è ṣọ fún-un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

Ka pipe ipin Oníwàásù 8