Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 7:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Orúkọ rere ṣàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ

2. Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ju ibi àṣènítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyànkí alààyè ní èyí ní ọkàn.

3. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọÓ le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le

4. Ọkàn ọlọgbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.

5. Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.

6. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkòni ẹ̀rín òmùgọ̀,Aṣán sì ni eléyìí pẹ̀lú.

7. Ìrẹ́jẹ a máa ṣọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.

8. Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,ṣùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.

9. Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹnítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.

10. Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti bèèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

11. Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún-ìní jẹ́ ohun tí ó dáraó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.

12. Ọgbọ́n jẹ́ ààbògẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbòṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyípé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá níi.

13. Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:“Ta ni ó le è toohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”

14. Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò óỌlọ́run tí ó dá èkínnínáà ni ó dá ìkejìnítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwáríohun kankan nípa ọjọ́ iwájúu rẹ̀.

15. Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí:Ènìyàn olóòtìítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.

16. Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọtàbí ọlọ́gbọ́n jùlọkí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?

Ka pipe ipin Oníwàásù 7