Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 5:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà tí ó bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pé ní mímú ṣẹ kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ.

5. Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ.

6. Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé-ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́?

7. Aṣán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

8. Bí o bá rí talákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú títì, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dùú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lá bẹ́ rẹ̀ lójú ni, ṣìbẹ́ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì.

9. Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.

10. Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùnpẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún-un.

11. Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ síináà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ síiÈrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí oní nǹkanbí kò se pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rírí wọn?

12. Oorun alágbàṣe a máa dùn,yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀kì í jẹ́ kí ó ṣùn rárá.

13. Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùnọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun oní nǹkan.

Ka pipe ipin Oníwàásù 5