Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 2:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá níṣinṣin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà já sí asán.

2. “Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ire-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?”

3. Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀,—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.

4. Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀.

5. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn.

Ka pipe ipin Oníwàásù 2