Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 10:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán-an.

9. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pe òkúta lẹ́jọ́ le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì-igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.

10. Bí àáké bá kútí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́nyóò nílò agbára púpọ̀ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.

11. Bí ejò bá sán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

12. Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.

13. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìṣínwín búburú.

14. Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀ta ni ó le è ṣọ fún-un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?

15. Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá lágbarakò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìgboro.

16. Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìranṣẹ́ rẹ̀àti tí àwọn ọmọ aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.

17. Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmọ̀tí para.

Ka pipe ipin Oníwàásù 10