Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 10:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún ìpara ní òórùn burúkú,bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.

2. Ọkàn ọlọgbọ́n a máa sí sí ohun tí ó tọ̀nà,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.

3. Kó dà bí ó ti ṣe ń rìn láàrin ọ̀nà,òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́na sì máa fi han gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.

4. Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,ma ṣe fi àyè rẹ sílẹ̀;ìdákẹ́jẹ́jẹ́ le è tu àṣìṣe ńlá.

5. Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.

6. A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jù lọ,nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn àyè tí ó kéré jù lọ.

7. Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,nígbà tí ọmọ aládé ń fi ẹṣẹ̀ rìn bí ẹrú.

8. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán-an.

9. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pe òkúta lẹ́jọ́ le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì-igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.

10. Bí àáké bá kútí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́nyóò nílò agbára púpọ̀ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.

Ka pipe ipin Oníwàásù 10