Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 8:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn àgbààgbà ẹ̀yà Éfúráímù sì bínú gidigidi sí Gídíónì wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa? Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Mídíánì jagun? Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀.

2. Ṣùgbọ́n Gídíónì dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fi wé tiyín? Àṣàkù àjàrà Éfúráímù kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Ábíésérì lọ bí?

3. Ọlọ́run ti fi Órébù àti Ṣéébù àwọn olórí àwọn ará Mídíánì lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Móṣè ṣe tí ó tó fi wé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín.” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọ lẹ̀.

4. Gídíónì àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀ṣíwájú láti lépa àwọn ọ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n dé Jọ́dánì wọ́n sì kọjá sí òdì kejì.

5. Ó wí fún àwọn ọkùnrin Ṣúkótì pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ ogun mi ní oúnjẹ diẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Ṣébà àti Ṣálímúnà àwọn ọba Mídíánì.”

6. Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Ṣúkótì fèsì pé ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Ṣébà àti Ṣálímúnà náà ni? Èéṣe tí àwa yóò ṣe fún àwọn ológun rẹ ní oúnjẹ?

7. Gídíónì dá wọn lóhùn pé, “Ó dára, nígbà tí Olúwa bá fi Ṣébà àti Ṣálímúnà lé mi lọ́wọ́ tán èmi yóò fi ẹ̀gún ìjù àti ẹ̀gún ọ̀gán ya ara yín.”

8. Láti ibẹ̀, ó lọ sí Péníélì ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Súkótì ti dá a lóhùn.

9. Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Péníélì pé, “Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé èmi yóò wọ ilé ìṣọ́ yìí.”

10. Ní àsìkò náà Ṣébà àti Ṣálímúnà wà ní Kákórì pẹ̀lú ọmọogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn, nítorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun.

11. Gídíónì gba ọ̀nà tí àwọn dáràndáràn máa ń rìn ní apá ìhà ìlà oòrùn Nóbà àti Jógíbíà ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀.

12. Ṣébà àti Ṣálímúnà, àwọn ọba Mídíánì méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gídíónì lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn.

13. Gídíónì ọmọ Jóásì gba ọ̀nà ìgòkè Hérésì padà sẹ́yìn láti ojú ogun.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 8