Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 5:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Dèbórà àti Bárákì ọmọ Ábínóámù kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé:

2. “Nítorí bí àwọn olórí ti ṣíwájú ní Ísírẹ́lì,nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa,Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!

3. “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ̀yin ìjòyè!Èmi yóò kọrin nípa Olúwa, èmi yóò kọrinÈmi yóò kọrin sí Olúwa: Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

4. “Olúwa nígbà tí o jáde lọ láti Ṣéírì,nígbà tí o yan láti ilẹ̀ Édómù,ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run ya,ìkúùkù àwọ̀sámọ̀ da omi wọn sílẹ̀.

5. Àwọn òkè mì tìtì ní iwájú Olúwa Ísírẹ́lì ẹni tí ó ni Ṣínáì,níwájú Olúwa ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

6. “Ní àwọn ọjọ́ Ṣámgárì ọmọ Ánátì,Ní àwọn ọjọ́ Jáélì, a kọ àwọn ojú ọ̀nà sílẹ̀;àwọn arìnrìnàjò ń gba kọ̀rọ̀ kọ́rọ́.

7. Àwọn akọni ìletò dínkù,wọ́n dínkù afi ìgbà tí Dèbórà dìde,ó dìde bí ìyá ní Ísírẹ́lì.

8. Nígbà tí Ísírẹ́lì bá yan Ọlọ́run àjèjì,ogun jíjà wọ ibodè ìlúa kò rí àpáta tàbí ọ̀kọ̀láàárin àwọn ẹgbàá ní Ísírẹ́lì

9. Inú mi yọ̀ sí àwọn aláṣẹ Ísírẹ́lìàwọn tí ó fi tínu tínu fi ara wọn rúbọẸ yín Olúwa!

10. “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,ẹ̀yin tí ń jókòó láti se ìdájọ́,àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà,Ní ọ̀nà jìnjìn sí

11. ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.Wọ́n ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa níbẹ̀,àní iṣẹ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwasọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibodè.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 5