Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 19:22-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Bélíálì kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kún; wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, “Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n.”

23. Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹyin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.

24. Kíyèsí i, ọmọbìnrin mi ni èyí, wúndíá, àti àlè rẹ̀; àwọn ni èmi ó mú jáde wá nísinsin yìí, kí ẹ̀yin tẹ̀ wọ́n lógo, kí ẹ̀yin ṣe sí wọn bí ó ti tọ́ lójú yín: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ̀yin má ṣe hùwa òmùgọ̀ yìí sí.”

25. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò fetí sí tirẹ̀. Torí náà ọkùnrin náà mú àlè rẹ̀ ó sì tari rẹ̀ jáde sí wọn, wọ́n sì bá a fi ipá lòpọ̀, wọ́n sì fi gbogbo òru náà bá a lòpọ̀, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́.

26. Nígbà tí ojúmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí là obìnrin náà padà lọ sí ilé tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó ṣubú lulẹ̀ lọ́nà, ó sì wà níbẹ̀ títí ó fi di òwúrọ̀.

27. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ jí tí ó sì dìde ní òwúrọ̀ tí ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé náà, tí ó sì bọ́ sí òde láti tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, kíyèsí i àlè rẹ̀ wà ní síṣubú ní iwájú ilé, tí ọwọ́ rẹ̀ sì di òpó ẹnu ọ̀nà ibẹ̀ mú,

28. òun sì wí fún obìnrin náà pé, “Dìde jẹ́ kí a máa bá ọ̀nà wa lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò dá a lóhùn. Nígbà náà ni ọkùnrin náà gbé e lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì kọjá lọ sí ilé e rẹ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 19