Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 18:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojú rere Ọlọ́run pàdé.”

7. Àwọn ọkùnrin máràrùn náà kúrò, wọ́n sì wá sí Láìsí, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Ṣídónì, láì sí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Ṣídónì, wọn kò fí ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀.

8. Nígbà tí wọ́n padà sí Ṣórà àti Ésítaólì, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí? Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá?”

9. Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀? Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ ṣíbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà.

10. Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ ó ò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.”

11. Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran Dánì, jáde lọ láti Sórà àti Ésítaólì ní mímú ra láti jagun.

12. Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kíríátì Jéárímì ní Júdà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀ oòrùn Kíríátì Jéárímù ni Máhánè Dánì títí di òní yìí.

13. Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Éfúráímù, wọ́n sì dé ilé Míkà.

14. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Láìsì wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní èwù Éfódì, àwọn yóòkù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.”

15. Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì náà, sí ilé Míkà, wọ́n kí i.

16. Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin ará Dánì náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 18