Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 18:12-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kíríátì Jéárímì ní Júdà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀ oòrùn Kíríátì Jéárímù ni Máhánè Dánì títí di òní yìí.

13. Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Éfúráímù, wọ́n sì dé ilé Míkà.

14. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Láìsì wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní èwù Éfódì, àwọn yóòkù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.”

15. Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì náà, sí ilé Míkà, wọ́n kí i.

16. Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin ará Dánì náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi.

17. Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, éfódì náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní àbáwọ ẹnu odi náà.

18. Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Míkà lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, éfódì náà, àwọn òrìsà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?”

19. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Ísírẹ́lì bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?”

20. Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú èfódì náà, àwọn òrìsà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ.

21. Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn ṣíwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ.

22. Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Míkà, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbégbé Míkà kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dánì bá.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 18